Sheik Adam Abdullah Al-Ilory
Ṣeik Adam Abdullah Al-Ilory |
---|
Ṣeik Adam Abdullah Al-Ilory ni wọ́n bí ní ọdún (1917-1992), sí ìdílé Ṣéù Abdul Baqi Al-Ilory. Ó jẹ́ àṣáájú onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú èsìn Islam ní orílẹ̀ èdè Benin-Nàìjíríà.
Ó jẹ́ ẹni tí ó tẹ̀lé ìlànà Imam Maliki, tí ó sì jẹ́ òǹkọ̀wé ìmọ̀ oríṣiríṣi nínú èdè Lárúbáwá (Arabic Author). Ó tún jẹ́ oní Súfi ní ìlànà Qadiriyya. Ó dá ilé ẹ̀kọ́ Markhazl-Uluum tí ó wà ní ìlú Agége, agbègbè kéréje kan ní ìpínlẹ̀ Èkó , ní ọdún 1945. Ilé ẹ̀kọ́ náà ní ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ kéú àti Kùránì tí tàn kálẹ̀ láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tó fí wọ Benin, àti gbogbo ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ adúláwọ̀ pátá
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bị́ Adam Abdullah Al-Ilory ní Wasa ní apá Gúsù orílẹ̀ èd̀e Benin , ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Benin tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá ọmọ orílẹ̀ èd̀e Nàìjíríà. Bàbá rẹ̀, Abdul Baqi, jẹ́ onímọ̀́ ìjìnlẹ̀ nípa Kùránì tí ó sì ma ń ṣe ìṣítí fún àwọn ènìyàn ní agbègb̀e dé agbègbè àti ìlú sí ìlú bíi: Ìbàdàn, Abẹ́òkúta, Ẹdẹ, Osogbo àti Wasa tí ó jẹ́ olú ìlụ́ orílẹ̀ èdè Benin lónìí, níbi tí wọ́n bí Adam al-Ilory sí ní ọdún 1917. Ní Ìlọrin, tí ó jẹ́ olú ìlú ìpìnlẹ̀ Kwara, ibẹ̀ ni Séù Adam al-Ilory ti parí ìmọ̀ Kùránì kíkà rẹ̀ tí ó sì ti mumi ìmọ ẹ̀kọ́ Kéú láti kọ́ àti mọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam. Wọ́n fàá sí ojú ọ̀nà Sufism ní ìl̀anà Qadiriyya, lábẹ́ ìkọ́ àti ìtọ́ Sheu Ahmad Roufai "Nda Salati" ní ọdún (1897-1966), ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ògbó-ǹ-tagì onímọ̀ nípa Sufi nílùú Ìlọrin lásìkò náà.[1] Ó dá ilé ẹ̀kọ́ Markhaz kalẹ̀ ní ọdún 1945, tí ó jẹ́ pé lónìí ilé ẹ̀kọ́ náà ti kọ́ àwọn ènìyàn nímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Lárúbáwá nìkan bí kò ṣe ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ pẹ̀lú.
Àwọn ìwé tí ó ti kọ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó tí kọ àwọn ìwé oríṣiríṣi àrímálè lọ àti àwò-pad̀a sẹ́yìn tí ó ń júwe ìmọ̀ fún gbogbo àgbáyé lónìí pẹ̀lú ẹ̀bùn ìmọ̀ nípa Kùránì. Sheu Adam kò ṣàì fi sílẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwé tí ó jẹ́ òtítọ́ àti òdodo tí ó kún fún ìmò ìjìnlẹ̀ tí ó sì tún lààmì laaka nínú èdè Lárúbáwá tí ó sì tún jẹ́ ohun ọ̀ṣ̀ọ́ láti ọwọ́ ọmó Yoruba sí ìmọ̀ Islam. Púpọ̀ nínú àwọn ìwé rẹ̀ ni ó dá lórí àwọn àkòrí bíi: Ikú, ìbáṣepọ̀ láàrín àṣà níl̀anà Imam Maliki, ìtàn ìgbésí ayé Sheu Abdul-Quadir al-Jilani , ẹ̀kọ́ nípa ìhùwàsí, ìmọ̀ nípa ìrìn-àjò ẹ̀mí, ètọ́ ọmọnìyàn, ìtàn ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀nà ìṣèjọba àti Gírámà Lárúbáwá. Lára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni:
1. Aseem Soba (Morning Breeze) 2. Markhaz Talimil Arabiy (Markhaz Center for Arabic Language Learning) 3. Ali Heedu Al'Arbahuna (Markhaz Center, 40 years old, 1985)
4. Aslu Koba il Yoruba (History of the Yoruba People) 5. El Islam Fi Naijiriyya (Islam in Nigeria) 6. Lamhada fi Barul al Ulama al-Ilory (Overview of the Scientists of the City of Ilorin) 7. Attarulilemi Watasowuf (Role of Science and Sufism in Islam) 8. Dahoru Tasowuwasofiyat (Purpose of Sufism) 9. Niusomtahalim Arabiy Wahlislamiy (Guide to Learning Islam and the Arabic Language) 10. Ukukuli Hinsanni (Human Rights) 11. Al Islamdinu Wadaholat (Islam and Government) 12. Al Islam Watakolid Jahili (Islam and the black race)
Ìdásílẹ̀ Markazil-Uluum
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n dá Markaz sílẹ̀ ní ọdún 1952 láti lè mú ọ̀làjú wọ inú ìmọ̀ kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ àti àṣà Lárụ́báwá káà-kiri ilẹ̀ Adúláwọ̀, pàá p̀aá jùlọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Kò tíì sí ẹnìkan nínú àwọn onímọ̀ Lárúbáwá ní àsìkò 20th century, bó yá ó ti kú tàbí tí ó wà láàyè tí ó ti gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó nípa tó́ lààmì laaka tó báyìí rí nínú ìt̀an àyàfi Sheu Adam. Èyí ló jẹ́ kí ilé-ẹ̀kọ́ Markaz ó dá dúró nípa kíkọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn nímọ̀ tó pegedé nípa ìlànà ètò ẹ̀kọ́ òde òní. Bákan náà, inú ilé ẹ̀kọ́ Markaz náà ní wọ́n ti kọ́kọ́ lo ẹfun-ìkọ̀wé àti pátákó ik̀ọwé sí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Lárúbáwá àti ẹ̀sìn Islam ní ìwọ̀ Oòr̀un Nàìjíríà. Yàtò sí pákó pélébé dúdú àti Tàdáà tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ tẹ́lẹ̀. Inú ilé ẹ̀kọ́ Markaz láàrín ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Islam tó kù ni wọn ti kọ́kọ́ ṣètò ìlànà ìkọ́ni tí ó ṣe àdáyanrí bí wọn yóò ṣe pín àwọn ọmọ sí iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tó y���. Bákan náà nínú Markaz ni àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Islam àti ẹ̀kọ́ Lárúbáwá ti kọ́kọ́ wọ aṣọ ìdánimọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ (schoo uniform), tí wọ́n sì ń jókòó lórí àga tí wọ́n sì tún kọ̀wé lórí tábìl̀i dípò orí ẹní tàbí ilẹ̀ lásán tí wọ́n sì ń lo gègé ìkọ̀wé àti ìwé pẹ̀lụ́. Ẹ̀wẹ̀, Markaz náà ni wọ́n ti kọ́kọ́ bẹ̀̀rẹ̀ ìlànà ìdánwò ẹ̀kọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lórí ohun tí wọ́n ti kọ́ wọn láti lè fi ṣe ìgbéléwọ̀n(assessment) , àti láti ṣe ìgbéga tàbí láti fìdí ẹni tí ó bá pàdánù rẹmi. Bákan náà ni wọ́n tún ṣàgbékalẹ̀ ìwé ẹ̀rí tó yanrantí fún àwọn tó bá kẹ́kọ̀ jáde nílé ẹ̀kọ́ náà. Markaz yìí kan náà ni a ti kọ́kọ́ rí àwọn ohun amáyé-dẹrùn bíi: ilé-ìgbé àwọn àkẹ́kọ̀(hostel), iyàrá tí akẹ́kọ̀ọ́ ti lè yá ìwé kà (Library), ìwé títẹ̀ jáde pẹ̀lú ilé ìwòsàn fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣàárẹ̀[2]
Ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́-jáde alákọ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́-jáde àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní Markaz wáyé ní ọdún 1957, inú àwọn ènìyàn sì dùn púp̀ọ láti rí irú ìyí padà rere báyìí, tí ó sì jẹ́ kí Sheu Adam ó di ìlú mọ̀ọ́ká àgbà oní mímọ̀ káà-kiri ayé. Lẹ́yìn ayẹyẹ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn Àfáà ni wọ́n gbà tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ilé-ẹ̀kọ́ náà láti kẹ́kọ̀ọ́ síwájú si nílànà ìgbàlódé.[3]
Lára àwọn Àfáà tí a mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀ ló wá láti onírúurú orílẹ̀ èdè tí ó sún mọ́ Nàìjíríà bíi: Benin Republic, Togo, Ghana, Cote de Voire, Guinea, Burkina Faso, Cameroon, Sierra Leone, Liberia ati Senegal. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde tán, wọn yóò sì tún padà sílù wọn láti dá irúf́ẹ ilé-ẹ̀kọ́ bí tí Markaz kalẹ̀ sí ìlú wọn lábẹ́ àṣẹ ilé-ẹ̀kọ́ Markaz Agége àti láti máa ṣe Àfáà wọn lọ.
Awon itoka si
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Who is Shaykh Adam Abdullah Al-Ilory?". The Nation Nigeria. 2018.
- ↑ "Sheikh Adam Al Ilory: Centenary celebrations begin April 15". Vanguard News. 2018-03-30. Retrieved 2018-05-31.
- ↑ "BIOGRAPHY OF SHEIKH MUSTAPHA ZUGLOOL SUNUUSI (1938 – 2017) – Know Islam". Know Islam – Know Islam, Know Paradise. 2015. Archived from the original on 2018-06-28.